11. Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Ṣakaríà. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.
12. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jéhù jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì títí dé ìran kẹrin.”
13. Ṣálúmù ọmọ Jábésì di ọba ní ọdún kọkàndínlógójì Ùsáyà ọba Júdà, ó sì jọba ní Ṣamáríà fún oṣù kan.
14. Nígbà náà Ménáhémù ọmọ Gádì lọ láti Tírísà sí Ṣamáríà. Ó dojúkọ Ṣalúmù ọmọ Jábésì ní Samáríà, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.
15. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣalúmù, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì.