2 Ọba 15:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n tí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, Ásáríyà ọmọ Ámásáyà ọba Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jọba.

2. Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rindínlógún nígbà tí o di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláàdọ́ta. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a má a jẹ́ Jékólíà; ó wá láti Jérúsálẹ́mù.

2 Ọba 15