7. Nígbà tí ìwé náà dé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ aládé bìnrin, wọ́n sì pa gbogbo àádọ́rin wọn. Wọ́n gbé orí i wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jéhù ní Jésérẹ́lì.
8. Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jéhù, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ aládé bìnrin náà wá.”Nígbà náà Jéhù pàṣẹ, “Kó wọn sí ẹ̀bú méjì sí àbáwọlé ìlẹ̀kùn ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.”
9. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jéhù jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí!?
10. Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Áhábù tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípaṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà.”
11. Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.
12. Jéhù jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Ṣamáríà. Ní Bẹti-Ékédì tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn.
13. Ó pàdé díẹ̀ lára àwọn ìbátan Áhásáyà ọba Júdà, ó sì béèrè, “Ta ni ẹ̀yin ń ṣe?”Wọ́n wí pé, “Àwa jẹ́ ìbátan Áhásáyà, àwa sì ti wá láti kí ìdílé ọba àti ti mọ̀mọ́ ayaba.”
14. “Mú wọn láàyè!” ó pàṣẹ. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n ní ẹ̀bá kọ̀nga Bẹti-Ékédì, ọkùnrin méjìlélógójì. Kò sì fi ẹnìkan sílẹ̀ láìkù.