2 Kọ́ríńtì 9:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀.

4. Kí ó má baà jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedóníà bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí.

5. Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ̀ bí ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti ìfipágbà.

6. Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kínún, kínún ni yóò ká; ẹní tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká.

7. Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọ̀kàn rẹ̀; kì í ṣe àfìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọ́dọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ.

8. Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo.

9. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:“Ó tí fọ́nká; ó ti fifún àwọn talákà;Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”

10. Ǹjẹ́ ẹni tí ń fí irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i.

2 Kọ́ríńtì 9