3. Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀ òdì sí.
4. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fí ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà,
5. nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìṣan, nínú ìgbààwẹ̀.
6. Nínú ìwà mímọ̀, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mi Mímọ̀, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn.
7. Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apa òsì.
8. Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìn rere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a já sí ólóòótọ́,
9. bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a si wà láàyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá,