2 Kọ́ríńtì 4:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọpẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.

16. Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa; ṣùgbọ́n bí ọkùnrin ti òde wa bá ń parun, ṣíbẹ̀ ọkùnrin tí inú wa ń di túntún lójoojúmọ́.

17. Nítorí ìpọ́njú díẹ̀ kíún yìí ń pèsè ògo tí ó ní ìwọ̀n ayérayè tí ó pọ̀ rékọjá sílẹ̀ fún wa.

18. Níwọ̀n bí kò ti wo ohun tí a ń rí, bí kò ṣé ohun tí a kò rí; nítorí ohun tí a ń rí ni ti ìgbà ìsinsin yìí; ṣùgbọ́n ohun tí a kò rí ni ti ayérayé.

2 Kọ́ríńtì 4