2 Kọ́ríńtì 3:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.

10. Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.

11. Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo.?

12. Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.

13. Kì í sì í ṣe bí Mósè, ẹni tí ó fí ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Ísríẹ́lì má baà lè tẹjú mọ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ

2 Kọ́ríńtì 3