2 Kọ́ríńtì 11:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30. Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi.

31. Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jésù Kírísítì, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké.

32. Ní Dámásíkù, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Árétà fí ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ara Dámásíkù mọ́, ó ń fẹ́ mi láti mú:

33. Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

2 Kọ́ríńtì 11