2 Kọ́ríńtì 11:14-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Sátanì, tìkáraarẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dà bí ańgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.

15. Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dà bí àwọn ìrànṣẹ́ òdodo; ìgbẹ́yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

16. Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀.

17. Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí.

18. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú.

19. Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkáraayín jẹ́ ọlọgbọ́n.

2 Kọ́ríńtì 11