2 Kọ́ríńtì 1:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí èyí ní ìsògo wá, ẹ̀rí láti inú ọkàn wa pẹ̀lú ìń jérìí wí pé àwa ń gbé ìgbésí ayé tí ó ní tumọ̀ pàápàá jùlọ nínú ìbágbépọ̀ wa pẹ̀lú yín, nínú ìwà mímọ́ àti òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kì í ṣe nípa ọgbọ́n ènìyàn ni àwa ń ṣe èyí bí kò ṣe nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

13. Nítorí pé àwa kò kọ̀wé ohun tí èyín kò lè kà mòye rẹ̀ sí yín. Mo sì tún ní ìrètí wí pé.

14. Gẹ́gẹ́ bí ẹyín pẹ̀lú ti ní ìmọ̀ nípa wa ní apákan, bákan náà ni ẹ ó ní ìmọ̀ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ tí ẹ ó sì fi wá yangàn, bí àwa pẹ̀lú yóò ṣe fi yín yangàn ní ọjọ́ Jésù Olúwa.

2 Kọ́ríńtì 1