2 Kíróníkà 5:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Sólómónì ti ṣe fún tẹ́ḿpìlì ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dáfìdì baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀sọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìsúra ilé Ọlọ́run.

2. Nígbà náà ni Sólómónì pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ sí Jérúsálẹ́mù, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Májẹ̀mu Olúwa gòkè wá láti síónì ìlú Dáfídì.

2 Kíróníkà 5