2 Kíróníkà 4:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ó ṣe ìgbe fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúsù àti márùn ún ní ìhà àríwá.

8. Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúṣù àti márùn ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́rún ọpọ́n ìbùwọ̀n wúrà.

9. Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ.

10. Ó gbé òkun náà ka orí ìhà gúsù ní ẹ̀bá Igun gúsù àríwá.

11. Ó ṣe àwọn kòkò pẹ̀lu, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n.Bẹ́ẹ̀ ni Húrámì parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Sólómónì ní ilé Ọlọ́run:

12. Àwọn òpó méje;àwọn ọpọ́n méjì rìbìtì tí ó wà lóri òpó méjèèje náà;àti ìṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì láti bo ọpọ́n rìbìtì náà tí ó wà lórí àwọn òpó naà;

13. Ọgọ́rùn ún mẹ́rin Pomígíránátì fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì naà, ẹṣẹ̀ méjì Pomigiranati ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lóri àwọn òpó náà;

14. Ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;

2 Kíróníkà 4