2 Kíróníkà 36:19-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Wọ́n sì fi iná sí ilé Ọlọ́run, wọ́n sì wó gbogbo ògiri ilé Jérúsálẹ́mù, wọ́n sì jó gbogbo ààfin wọn, wọ́n sì ba gbogbo ohun-èlò ibẹ̀ jẹ́.

20. Ó sì kó èyí tí ó kù lọ sí Bábílónì àwọn tí ó rí ibi sá láti ẹnu idà wọ́n sì di ìránṣẹ́ fún un àti àwọn ọmọ rẹ̀ títí tí ìjọba Pásíà fi gba agbára.

21. Ìlẹ̀ náà sì gbádùn ìsinmi rẹ̀, ní gbogbo ìgbà ìdahoro, òun sì ń sinmi títí ó fi di àádọ́rin ọdún (70) fi pé ní ìmúsẹ ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ láti ẹnu Jeremíà.

2 Kíróníkà 36