2. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn.
3. Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Heṣekáyà ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Báálì ó sì ṣe àwọn òpó Áṣérà. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n.
4. Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé Olúwa ní èyí tí Olúwa ti wí pé “Orúkọ mi yóò wà ní Jérúsálẹ́mù títí láé.”
5. Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run
6. Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rúbọ nínú iná ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Bẹni-Hínómù, ó ń ṣe oṣó, àfọ̀ṣẹ, ìsàjẹ́ pẹ̀lú bíbéèrè lọ́dọ̀ àwọn abókúsọ̀rọ̀, àti ẹlẹ́mìí. O se ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.