2 Kíróníkà 32:32-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Gbogbo iṣẹ́ yòókù ti ìjọba Heṣekíà àti àwọn ìṣe rẹ̀, ìfarajì rẹ̀ ni a kọ sínú ìwé ìran wòlíì Àìṣáyà ọmọ Ámósì nínú ìwé àwọn ọba Júdà àti Ìsírẹ́lì

33. Heṣekáyà sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin-ín sórí òkè níbi tí àwọn ibojì àwọn àtẹ̀lé Dáfídì wà. Gbogbo Júdà àti àwọn ènìyàn Jérúsálẹ́mù ni ó bu ọlá fún un nígbà tí ó kú. Mánásè ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

2 Kíróníkà 32