2 Kíróníkà 3:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ní ìjọra, ìyẹ́ apá kan ní ti kérúbù kejì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gígùn, ó sì farakan ògiri ilé Olúwa mìíràn; ìyẹ́ apá rẹ̀ mìíràn sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn ní gígùn pẹ̀lú. Tí ó farakan ìyẹ́ apá kérúbù àkọ́kọ́.

13. Ìyẹ́ apá àwọn kérúbù wọ̀nyìí gbà tó ogún ìgbọ̀nwọ́. Wọ́n dúró ní ẹsẹ̀ wọn, wọ́n kọjú sí yàrá pàtàkì ńlá naà.

14. Ó ṣe aṣọ títa ní àwọ̀ ojú ọ̀run, àwọ̀ àlùkò àti àwọ̀ pupa fòò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ pẹ̀lú kérúbù tí a se sórí i rẹ̀.

2 Kíróníkà 3