2 Kíróníkà 26:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ùsáyà sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjìléláadọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekolíà; ó sì wá láti Jérúsálẹ́mù.

4. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Ámásíà ti ṣe.

5. Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekaríà, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ̀n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún-un ní ohun rere.

6. Ó sì lọ sí ogun lórí Fílístínì ó sì wó odi Gátì lulẹ̀, Jábìnè àti Ásídódù. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Ásídódù àti níbì kan láàrin àwọn ará Fílístínì.

7. Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lóri àwọn ará Fílístínì àti Árábù tí ń gbé ní Gúrì Bálì àti lórí àwọn ará Méhúmì.

2 Kíróníkà 26