2 Kíróníkà 25:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Bẹ́ẹ̀ ni Jóásì, ọba Ísírẹ́lì: òun àti Ámásíà ọba Júdà dojúkọ ara wọn ní Bẹti Ṣeméṣì ní Júdà.

22. Àwọn ọmọ Ísirẹ́lì da Júdà rú, gbogbo olúkúlùkù ènìyàn sì sálọ sí ìlú rẹ̀.

23. Jóásì ọba Ísírẹ́lì fi agbára mú Áhásáyà ọba Júdà, ọmọ Jóáṣì ọmọ Áhásáyà ní Bétì Ṣéméṣì. Nígbà náà Jóásì mú u wá sí Jérúsálẹ́mù. Ó sì wó ògiri Jérúsálẹ́mù lulẹ̀ láti ẹnu ọ̀nà Éfíráímù sí igun ẹnu ọ̀nà apá kan títí ń lọ sí ọgọ́rùnún mẹ́fà ẹsẹ̀ bàtà ní gígùn.

24. Ó kó gbogbo wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò tí wọ́n rí ni ile Ọlọ́run tí ọ́ wà ní àbojútó Obedi Édómù, lápapọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣura ààfin àti àwọn ìdógó, ó sì padà sí Saaríà.

2 Kíróníkà 25