1. Sólómónì pinnu láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa àti ilé kan fún ìjọba rẹ̀
2. Sólómónì sì yan ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà àádọ́rin àwọn (70,000) ọkùnrin láti ru ẹrù àti ẹgbẹ̀rún ní ọ̀nà ọgọ́rin àwọn (80,000) ọkùnrin gẹ́gẹ́ bi olùgé-òkúta ní àwọn òkè àti ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì (36,000) gẹ́gẹ́ bí àwọn alábojútó lórí wọn.