2 Kíróníkà 19:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Jéhóṣáfátì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù ó sì jáde lọ padà láàárin àwọn ènìyàn láti Béríṣébà dé òkè ìlú Éfúráímù, ó sì mú wọn padà sọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run baba wọn.

5. Ó sì yan àwọn onídàájọ́ sí ilẹ̀ náà, ní olúkúlùkù ìlú olódi, Júdà.

6. Ó sì wí fun wọ́n pé, “Ẹ kíyèsí ohun tí ẹ̀yin ń ṣe, nítorí ìwọ kò ṣe ìdájọ́ fun ènìyàn ṣùgbọ́n fún Olúwa, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ ní ìdájọ́.

2 Kíróníkà 19