26. Ó sì wí pé ‘Èyí ni ohun tí ọba sọ: ẹ fi ènìyàn yìí sínú túbú kí ẹ má sì ṣe fún-un ní ohunkóhun ṣùgbọ́n àkàrà àti omi títí tí èmi yóò fi dé ní àlàáfíà.’ ”
27. Míkáyà sì wí pe, “Tí ìwọ bá padà ní àlàáfíà, Olúwa kò sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà náà, ó sì fi kún-un pé, “Ẹgbọ́ ọ̀rọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn!”
28. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jéhóṣáfátì ọba Júdà lọ sókè ní Rámótì Gílíádì.