12. Wọ́n sì tún dá májẹ̀mú láti wá Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn tinútinú wọn àti tọkàntọkàn wọn.
13. Pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wá Olúwa Ọlọ́run Isirẹ́lì, pípa ni á ó paá láti ẹni kékeré dé orí ẹni ńlá àti ọkùnrin àti obìnrin.
14. Wọ́n sì búra ní ohùn rara fún Olúwa àti pẹ̀lú ìhó nla àti pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú fèrè.
15. Gbogbo Júdà yọ̀ nípa ìbúra náà nítorí wọ́n ti búra tinútinú wọn wọ́n sì fi gbogbo ìfẹ́ inú wọn wá a, wọ́n sì rí i, Olúwa sì fún wọn ní ìsinmi yí káàkiri