2 Kíróníkà 14:14-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Wọ́n pa gbogbo àwọn ìletò tí ó wà ní ẹ̀bá Gérárì, nítorí tí ìpayà Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ sórí wọn. Wọ́n kó gbogbo ìkógún àwọn ìletò yìí lọ, níwọ̀n ìgbà tí ọ̀pọ̀ ìkógun ti wà níbẹ̀.

15. Wọ́n kọ lu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́-ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ. Nígbà náà wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù.

2 Kíróníkà 14