2 Kíróníkà 12:2-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí tí wọn kò ṣọ̀ọ́tọ́ sí Olúwa. Ṣíṣákì ọba Ị́jíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù ní ọdún karùnún ti ọba Réhóbóamù

3. Pẹ̀lú ẹgbẹ̀fà kẹ̀kẹ́ (12, 000) àti ọkẹ́ mẹ́ta àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Líbíyánì, Ṣúkísè àti Kúṣì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Éjíbítì.

4. Ó fi agbára mú àwọn ìlú ààbò ti Júdà, pẹ̀lú wá sí Jérúsálẹ́mù bí ó ti jìnnà tó.

2 Kíróníkà 12