2 Kíróníkà 11:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ó bí àwọn ọmọ fún un: Jéúṣì, Ṣémáríà àti Ṣáhámì.

20. Nígbà náà ó fẹ́ Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù, tí ó bí Ábíjà fún Átáì, Ṣíṣà àti Ṣélómítì.

21. Réhóbóámù fẹ́ràn Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju èyí kejì nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.

22. Réhóbóámù yan Ábíjà ọmọ Mákà láti jẹ́ olóyè ọmọ aládé láàárin àwọn arákùnrin rẹ̀, kí ó ba à lè ṣe é ní ọba.

2 Kíróníkà 11