2 Kíróníkà 10:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Bẹ́ẹ̀ ni ọba kò sì tẹ́tísi àwọn ènìyàn, nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni. Láti mú ọ̀rọ̀ Olúwa ṣẹ tí a ti sọ fún Jéróbóámù ọmọ Nébátì nípasẹ̀ Áhíjà ará Ṣilò.

16. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé:“Ìpín kí ní a ní nínú Dáfídì,ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jésè?Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ìwọ Ísírẹ́lì!Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dáfídì!”Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ilé wọn.

17. Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ń gbé ní ìlú Júdà, Réhóbóámù pàpà ń jọba lórí wọn.

18. Ọba Réhóbóámù rán Ádónírámù jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúuru, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Réhóbóámù bí ó tí wù kí ó rí, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jérúsálẹ́mù.

19. Bẹ́ẹ̀ ni Ísírẹ́lì sì wà ní ìsọ̀tẹ̀ lórí ilé Dáfídì títí fi di òní yìí.

2 Kíróníkà 10