1. Alàgbà,Sì àyànfẹ́ obìnrin-ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmí nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú;
2. nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.
3. Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlààáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jésù Kírísítì, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.