1 Tímótíù 5:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bíi bàbá; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin.

2. Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.

3. Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́.

1 Tímótíù 5