1 Tímótíù 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, bí ẹnìkan bá fẹ́ ipò Bíṣọ́ọ̀bù, iṣẹ́ rere ni ó ń fẹ́,

2. Ǹjẹ́ Bíṣọ́ọ̀bù yẹ kí ó jẹ́ aláìlẹ́gàn, ọkọ aya kan, olùsọ̀ràn, aláìrékọjá, oníwà yíyẹ, olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, ẹni tí ó lè ṣe olùkọ́.

3. Kí ó má jẹ́ ọ̀mùtí, tàbí alu-ni, tàbí olójúkòkòrò, bí kò ṣe onísùúrù, kí ó má jẹ́ oníjà, tàbí olùfẹ́ owó.

4. Ẹni tí ó káwọ́ ilé ara rẹ̀ gírígírí, tí ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ tẹríba pẹ̀lú ìwà àgbà gbogbo;

5. Ṣùgbọ́n bí ènìyàn kò bá mọ̀ bí a ti ń ṣe ìkáwọ́ ilé ara rẹ̀, òun ó há ti ṣe lè tọ́jú ìjọ Ọlọ́run?

1 Tímótíù 3