1 Tẹsalóníkà 3:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Kò ṣé é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín.

10. Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti se àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.

11. À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jésù Kírísítì láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í.

12. A sì béérè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì ṣàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà se sàn kan ẹ̀yin náà.

13. Nípa èyí, ọkàn yín yóò di alágbára, àìlẹ́sẹ̀ àti Mímọ́ nípa Ọlọ́run, Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jésù Kírísítì yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.

1 Tẹsalóníkà 3