7. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsinyìí pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa.
8. Kò sí nǹkan tí a kò lè fi ara dà níwọ̀n ìgbà tí a ti mọ̀ pé, ẹ̀yin sì dúró gbọn-ingbọn-in fún Olúwa.
9. Kò ṣé é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín.
10. Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti se àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.