4. Bẹ́ẹ̀ ní ó kọjá láàrin àwọn ìlú olókè Éfúráímù, ó sì kọja ní àyíká ilẹ̀ Sálísà, ṣùgbọ́n wọn kò rí wọn. Wọ́n sì kọjá lọ sí òpópó Sálímù, ṣùgbọ́n àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kò sí níbẹ̀. Nígbà náà, ó kọjá ní agbègbè Bẹ́ńjámínì, wọn kò sì rí wọn.
5. Nígbà tí wọ́n dé agbégbé Ṣúfù, Ṣọ́ọ̀lù sọ fún ìránṣẹ́ tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Wá, jẹ́ kí á padà sẹ́yìn, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, baba mi yóò dá ìrònú rẹ̀ dúró nípa àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yóò sì bẹ̀rẹ̀ àníyàn nípa wa.”
6. Ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ náà fún un ní èsì pé, “Wò ó, ní inú ìlú yìí ọkùnrin ènìyàn Ọlọ́run kan wà; ó jẹ́ ẹni tí wọ́n ń bu ọlá fún, àti gbogbo ohun tí ó bá sọ ní ó máa ń jẹ́ òtítọ́. Jẹ́ kí á lọ ṣíbẹ̀ nísinsin yìí, bóyá yóò sọ fún wá ọ̀nà tí a ó ò gbà.”