8. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Éjíbítì títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ.
9. Nísinsìn yìí, gbọ́ ti wọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáadáa, kí o sì jẹ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”
10. Sámúẹ́lì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀.
11. Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́sin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀.