1 Sámúẹ́lì 7:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà àwọn ará Kiriáti-Jéárímù wá, wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. Wọ́n gbé e lọ sí ilé Ábínádábù lórí òkè, wọ́n sì ya Élíásérì ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti ṣọ́ àpótí ẹ̀rí Olúwa.

2. Ó sì jẹ́ ní ìgbà pípẹ́, ogún ọdún ni àpótí ẹ̀rí Olúwa fi wà ní Kiriati Jéárímù. Gbogbo ilé Ísírẹ́lì ṣọ̀fọ̀ wọ́n sì pohùn réré ẹkún sí Olúwa.

1 Sámúẹ́lì 7