1 Sámúẹ́lì 4:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Bí ó ti ń kú lọ, obìnrin tí ó dúró tì í wí pé, “má ṣe bẹ̀rù; nítorí o ti bí ọmọ ọkùnrin.” Ṣùgbọ́n kò sọ̀rọ̀ tàbí kọ ibi ara sí i.

21. Ó sì pe ọmọ náà ní Íkábódù, wí pé, “Kò sí ògo fún Ísírẹ́lì mọ́” nítorí tí wọ́n ti gba àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run àti ikú baba ọkọ rẹ̀ àti ti ọkọ rẹ̀.

22. Ó si wí pé, “Ogo kò sí fún Isirẹli mọ́, nítorí ti a ti gbá àpótí Ọlọ́run”

1 Sámúẹ́lì 4