1 Sámúẹ́lì 31:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nígbà tí àwọn ará Jabesi-Gílíádì sì gbọ́ èyí tí àwọn Fílístínì ṣe sí Ṣọ́ọ̀lù.

12. Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Ṣọ́ọ̀lù, àti okú àwọn ọmọ bibi rẹ̀ kúrò lára odi Bétísánì, wọ́n sì wá sí Jábésì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀.

13. Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi kan ní Jábésì, wọ́n sì gba ààwẹ̀ ní ijọ́ méje.

1 Sámúẹ́lì 31