1 Sámúẹ́lì 30:20-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Dáfídì sì kó gbogbo àgùntàn, àti màlúù tí àwọn ènìyàn rẹ̀ dà ṣáàjú àwọn ohun mìíràn tí wọ́n gbà, wọ́n sì wí pé, “Èyí yìí ni ìkógun ti Dáfídì.”

21. Dáfídì sì wá sọ́dọ̀ igba ọkùnrin tí àárẹ̀ ti mú jú, ti wọn kò lè tọ́ Dáfídì lẹ́yin mọ́, ti òun ti fi sílẹ̀, ni odò Bésórì: wọ́n sì lọ pàdé Dáfídì, àti láti pàdé àwọn ènìyàn tí ó lọ pẹ̀lú rẹ̀: Dáfídì sì pàdé àwọn ènìyàn náà, ó sì kí wọn.

22. Gbogbo àwọn ènìyàn búburú àti àwọn ọmọ Bélíálì nínú àwọn tí o bá Dáfídì lọ sì dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Bí wọn kò ti bá wa lọ, àwa ki yóò fi nǹkan kan fún wọn nínú ìkógun ti àwa rí gbà bí kò ṣe obìnrin olúkúlùkù wọn, àti ọmọ wọn; ki wọn sì mú wọn, ki wọn sì máa lọ.”

23. Dáfídì sì wí pé, “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ara mi: Olúwa ni ó fi nǹkan yìí fún wa, òun ni ó sì pa wá mọ́, òun ni ó sì fi ẹgbẹ́-ogun ti ó dìde sí wa lé wa lọ́wọ́.

1 Sámúẹ́lì 30