1 Sámúẹ́lì 28:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ṣọ́ọ̀lù sì pa ara dà, ó sì mú aṣọ mìíràn wọ̀, ó sì lọ, àwọn ọmọkùnrin méjì sì pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ obìnrin náà lóru: òun sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, fi ẹ̀mí abókúsọ̀rọ̀ wo nǹkan fún mi, kí o sì mú ẹni tí èmí ó dárúkọ rẹ̀ fún ọ wá sókè fún mi.”

9. Obìnrin náà sì dá a lóhùn pé “Wò ó, ìwọ sáà mọ ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ṣe, bí òun ti gé àwọn abókúsọ̀rọ̀ obìnrin, àti àwọn abókúsọ̀rọ̀ ọkùnrin kúrò ní ilẹ̀ náà; ǹjẹ́ èé ha ṣe tí ìwọ dẹ́kùn fún ẹ̀mí mi, láti mú kí wọ́n pa mí.”

10. Ṣọ́ọ̀lù sì búra fún un nípa Olúwa pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ìyà kan kì yóò jẹ́ ọ́ nítorí nǹkan yìí.”

11. Obìnrin náà sì bi í pé, “Ta ni ẹ̀mí ó mú wá sókè fún ọ?”Òun sì wí pé, “Mú Sámúẹ́lì gòkè wá fún mi.”

1 Sámúẹ́lì 28