12. Dáfídì sì mú ọ̀kọ̀ náà àti ìgò omi náà kúrò níbi tìmùtìmù Ṣọ́ọ̀lù: wọ́n sì bá tiwọn lọ, kò sì sí ẹnìkan tí ó rí i, tàbí tí ó mọ̀: kò sì sí ẹnikàn tí ó jí; gbogbo wọn sì sùn; nítorí pé oorun ìjìká láti ọdọ Olúwa wá ti ṣubú lù wọ́n.
13. Dáfídì sì rékọjá sí ìhà kejì, ó sì dúró lórí òkè kan tí ó jìnnà réré; àlàfo kan sì wà láàrin méjì wọn:
14. Dáfídì sì kọ sí àwọn ènìyàn náà àti sí Ábínérì ọmọ Nérì wí pé, “Ìwọ kò dáhùn, Ábínérì?”Nígbà náà ni Ábínérì sì dáhùn wí pé, “Ìwọ ta ni ń pe ọba?”
15. Dáfídì sì wí fún Ábínérì pé, “Alágbára ọkùnrin kọ́ ni ìwọ bí? Ta ni ó sì dàbí ìwọ ni Ísírẹ́lì? Ǹjẹ́ èéṣe tí ìwọ kò tọ́jú ọba Olúwa rẹ? Nítorí ẹnìkan nínú àwọn ènìyàn náà ti wọlé wá láti pa ọba Olúwa rẹ.