7. A sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé Dáfídì wá sí Kéílà. Ṣọ́ọ̀lù sì wí pé, “Ọlọ́run ti fi í lé mi lọ́wọ́; nítorí tí ó ti sé ara rẹ̀ mọ́ ní ti wíwá tí ó wá sí ìlú tí ó ní ìlẹ̀kùn àti kẹrẹ.”
8. Ṣọ́ọ̀lù sì pe gbogbo àwọn ènìyàn náà jọ sí ogun, láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí Kéílà, láti ká Dáfídì mọ́ àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.
9. Dáfídì sì mọ̀ pé Ṣọ́ọ̀lù ti gbèrò búburú sí òun; ó sì wí fún Ábíátarì àlùfáà náà pé, “Mú éfódù náà wá níhínìnyìí!”
10. Dáfídì sì wí pé, “Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Lóòótọ́ ni ìránṣẹ́ rẹ ti gbọ́ pé Ṣọ́ọ̀lù ń wá ọ̀nà láti wá sí Kéílà, láti wá fọ́ ìlú náà nítorí mi.