1 Sámúẹ́lì 2:30-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. “Nítorí náà Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.

31. Kíyèsí i, àwọn ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi ó gé agbára rẹ kúrò, àti agbára baba rẹ, tí kì yóò sí arúgbó kan nínú ilé rẹ.

32. Nínú wàhálà ni ìwọ yóò fí ìlará wó gbogbo ọlá ti Ọlọ́run yóò fi fún Ísírẹ́lì; kì yóò sì sí arúgbó kan nínú ilé baba rẹ láéláé.

1 Sámúẹ́lì 2