23. Nítorí pé ìṣọ̀tẹ̀ dàbí ẹ̀ṣẹ̀ àfọ̀ṣẹ,àti ìgbéraga bí ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà.Nítorí tí ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa,Òun sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba.”
24. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún Sámúẹ́lì pé, “Èmi ti ṣẹ̀. Mo ti rú òfin Olúwa àti ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èmi sì bẹ̀rù àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni èmi sì gba ohùn wọn gbọ́.
25. Mo bẹ̀ ọ́ nísinsìn yìí, dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jìn, kí ó sì yípadà pẹ̀lú mi, kí èmi kí ó lè sin Olúwa.”
26. Ṣùgbọ́n Sámúẹ́lì wí fún un pé, “Èmi kò ní bá ọ padà. Ìwọ ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa sílẹ̀, Olúwa sì ti kọ̀ ọ́ ní ọba lórí Ísírẹ́lì!”