1. Sámúẹ́lì wí fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi ni Olúwa rán láti fi àmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì; fetí sílẹ̀ láti gbọ́ Iṣẹ́ tí Olúwa rán mi sí ọ́.
2. Èyí ni ohun tí Olúwa alágbára wí: Èmi yóò jẹ àwọn Ámálékì níyà fún ohun tí wọ́n ti ṣe sí Ísírẹ́lì nígbà tí wọn dè wọn lọ́nà nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Éjíbítì.
3. Lọ nísinsìn yìí, kí o sì kọlu Ámálékì, kí o sì pa gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ ti wọn ní àparun. Má ṣe dá wọn sí, pa ọkùnrin àti obìnrin wọn, ọmọ kékeré àti ọmọ ọmú, màlúù àti àgùntàn, ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn.”