1 Sámúẹ́lì 14:47-52 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

47. Lẹ́yìn ìgbà tí Ṣọ́ọ̀lù ti jọba lórí Ísírẹ́lì, ó sì bá gbogbo ọ̀tá wọn jà yíká: Móábù àti àwọn ọmọ Ámónì; Édómù, àti àwọn ọba Ṣọ́bà, àti àwọn Fílístínì. Ibikíbi tí ó bá kọjú sí, ó máa ń fi ìyà jẹ wọ́n.

48. Ó sì jà tagbáratagbára, ó ṣẹ́gun àwọn Ámálékì, ó sì ń gba Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí ó ń kọlù wọ́n.

49. Àwọn ọmọ Sọ́ọ̀lù sì ni Jónátánì, Ísúì àti Málíkísúà. Orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà sì ni Mérábù àti orúkọ ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré ni Míkálì.

50. Orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Áhínóámù ọmọbìnrin Áhímásì. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ábínérì ọmọ Nérì arákùnrin baba Sọ́ọ̀lù.

51. Kíṣì baba Ṣọ́ọ̀lù àti Ábínérì baba Nérì sì jẹ́ ọmọ Ábíélì.

52. Ní gbogbo ọjọ́ Ṣọ́ọ̀lù, ogun náà sì gbóná sí àwọn Fílístínì, níbikíbi tí Ṣọ́ọ̀lù bá sì ti rí alágbára tàbí akíkanjú ọkùnrin, a sì mú u láti máa bá a ṣiṣẹ́.

1 Sámúẹ́lì 14