1 Sámúẹ́lì 12:5-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Samúẹ́lì sì wí fún wọn pé, “Olúwa ni ẹlẹ́rìí sí i yín, àti ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ̀yin kò rí ohunkóhun lọ́wọ́ mi.”Wọ́n sì sọ wí pé, “Òun ni ẹlẹ́rìí.”

6. Nígbà náà ni Sámúẹ́lì wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Olúwa ni ó yan Mósè àti Árónì àti ti ó mú àwọn baba ńlá yín gòkè wá láti Éjíbítì.

7. Nísinsin yìí, ẹ dúró níbi, nítorí èmi ń lọ láti bá a yín sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa ní ti gbogbo ìṣe òdodo rẹ̀ tí ó ti ṣe fún un yín àti fún àwọn baba yín.

1 Sámúẹ́lì 12