1. Sámúẹ́lì sì mú ìgò kékeré tí òróró wà nínú rẹ̀, ó sì dà á sí orí Ṣọ́ọ̀lù. Ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu, wí pé, “Olúwa kò ha tí fi òróró yàn ọ ní olóri í lórí ohun ìní rẹ̀?
2. Bí ìwọ bá kúrò lọ́dọ̀ mi lónìí, ìwọ yóò bá ọkùnrin méjì pàdé lẹ́bàá ibojì Rákélì ní Sélísà, ní agbégbé Bẹ́ńjámínì. Wọ́n yóò sọ fún ọ pé, ‘Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ìwọ jáde lọ láti wá ní wọn tí rí. Nísinsìn yìí, baba à rẹ tí dákẹ́ kò ronú nípa wọn mọ́, ó sì ń damú nípa à rẹ. Ó ń béèrè, “Kí ni èmi yóò ṣe nípà ọmọ mi?” ’
3. “Nígbà náà, ìwọ yóò lọ láti ibẹ̀ títí yóò fi dé ibi igi Tábórì ńlá. Ọkùnrin mẹ́ta tí wọ́n ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní Bẹ́tẹ́lì yóò pàdé rẹ níbẹ̀. Ọ̀kan yóò mú ọmọ ewúrẹ́ mẹ́ta lọ́wọ́, èkejì, iṣù àkàrà mẹ́ta àti ẹ̀kẹtà yóò mú ìgò wáìnì.