1. Ọkùnrin kan wà, láti Rámátaímù-Sófímù, láti ìlú olókè Éfúráímù, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elikánà, ọmọ Jéróhámù, ọmọ Élíhù, ọmọ Tóhù, ọmọ Súfù, ará Éfírátà.
2. Ó sì ní ìyàwó méjì: orúkọ wọn ni Hánà àti Pẹ̀nínà: Pẹ̀nínà ní ọmọ, ṣùgbọ́n Hánà kò ní.
3. Ní ọdọọdún, ọkùnrin yìí máa ń gòkè láti ìlú rẹ̀ láti lọ sìn àti láti ṣe ìrúbọ sí Olúwa alágbára jùlọ ní Ṣílò, níbi tí àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fínéhásì ti jẹ́ àlùfáà Olúwa.