1 Pétérù 1:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnikejì yín gidigidi láti ọkàn wá.

23. Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láàyè tí ó sì dúró.

24. Nítorí pé,“Gbogbo ènìyàn dàbí kóríko,àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,

25. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìn rere tí a wàásù fún yín.

1 Pétérù 1