1 Ọba 9:26-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Sólómónì ọba sì tún ṣe òwò ọkọ̀ ní Esioni-Gébérì, tí ó wà ní ẹ̀bá Élátì ní Édómù, létí òkun pupa.

27. Hírámù sì rán àwọn ènìyàn rẹ̀, àwọn atukọ̀ tí ó mọ òkun, pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì.

28. Wọ́n sì dé ófírì, wọ́n sì mú irínwó ó lé ogún (420) talẹ́ǹtì wúrà, tí wọ́n ti gbà wá fún Sólómónì ọba.

1 Ọba 9