1 Ọba 8:65-66 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

65. Bẹ́ẹ̀ ni Sólómónì ṣe àpèjọ nígbà náà, àti gbogbo Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, àjọ ńlá ńlá ni, láti ìwọ Hámátì títí dé odò Éjíbítì. Wọ́n sì sàjọyọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ijọ́ méje àti ijọ́ méje sí i, ọjọ́ mẹ́rìnlá papọ̀.

66. Ní ọjọ́ kẹjọ ó rán àwọn ènìyàn lọ. Wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì lọ sí ilé wọn pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn fún gbogbo ohun rere tí Olúwa ti ṣe fún Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀, àti fún Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.

1 Ọba 8